Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wave Offering

30 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́.)

  2. Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan.

  3. Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

  4. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa.

  5. Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

  6. “Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀.

  7. Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

  8. Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú ìwúkàrà. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.

  9. “Èyí ni ọrẹ tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa ní ọjọ́ tí a bá fi òróró yan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára fún ẹbọ ohun jíjẹ lójoojúmọ́, ìdajì rẹ̀ ní àárọ̀ àti ìdajì rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́.

  10. Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífì.

  11. Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀,

  12. Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Israẹli, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Aaroni àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Israẹli.’ ”

  13. Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.

  14. Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.

  15. Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

  16. Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa.

  17. Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  18. Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

  19. Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ.

  20. Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú Olúwa àti itan tí wọ́n gbé síwájú Olúwa, kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Israẹli.

  21. Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le è fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí Olúwa ṣe pàṣẹ.”

  22. “Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti lógù òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Kí ó sì fì wọ́n níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì.

  23. Àlùfáà náà yóò sì mú ọ̀dọ́-àgùntàn ẹbọ ẹ̀bi pẹ̀lú lógù òróró yóò sì fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì.

  24. “Sọ fún àwọn ará Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírí ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.

  25. Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.