Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wave Offering

30 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí àlùfáà fi ọ̀dọ́-àgùntàn méjèèjì náà níwájú Olúwa bí i ọrẹ fífì pẹ̀lú oúnjẹ àkọ́so wọn jẹ́ ọrẹ mímọ́ sí Olúwa fún àlùfáà.

  2. Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.

  3. Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.

  4. “ ‘Lẹ́yìn tí Nasiri bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

  5. “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́.