Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Virgin

35 ẹsẹ · 10 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀ fún fífẹ́ ẹ ní wúńdíá.

  2. Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

  3. Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kórìíra rẹ̀,

  4. tí ó ṣì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i, tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo súnmọ́ ọn. Èmi kò rí àmì ìbálé rẹ̀.”

  5. Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè.

  6. Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀.

  7. Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú,

  8. àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà.

  9. Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.

  10. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà,

  11. wọn yóò mú wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli nípa ṣíṣe àgbèrè nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín yín.

  12. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàdé wúńdíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrín ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀,

  13. ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní òkúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.

  14. Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láààyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n sọkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúńdíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.”

  15. Jefta dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láààyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yòókù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n sọkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó.

  16. Lẹ́yìn oṣù méjì náà, ó padà tọ baba rẹ̀ wá òun sì ṣe sí i bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti jẹ́. Ọmọ náà sì jẹ́ wúńdíá tí kò mọ ọkùnrin rí. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ àṣà kan ní Israẹli

  17. Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀, nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.

  18. Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli.

  19. Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn, àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú, òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.

  20. Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

  21. “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”).

  22. “Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó.

  23. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n.

  24. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́.

  25. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn.