Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vail or Veil

14 ẹsẹ · 9 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. ó sì béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ náà wí pé, “Ta ni ọkùnrin tí ń bọ̀ wá pàdé wa láti inú oko?” Ìránṣẹ́ náà sì wí fun un pé, “Olúwa mi ni,” nítorí náà ni Rebeka mú ìbòjú, ó sì bo ojú rẹ̀.

  2. Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.

  3. Nígbà tí Mose parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.

  4. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

  5. dígí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

  6. Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,

  7. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kristi sì ní Ọlọ́run.

  8. Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un láti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.

  9. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.

  10. Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn angẹli, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.

  11. Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ.

  12. Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.

  13. Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkígbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn.

  14. Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.