Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tribe Of Ephraim: Bounds of its inheritance
Àwọn ẹsẹ nípa Bounds of its inheritance
Èyí ni ilẹ̀ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé. Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Addari ní ìlà-oòrùn lọ sí òkè Beti-Horoni.
Ó sì lọ títí dé Òkun. Láti Mikmeta ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Ṣilo, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Janoa ní ìlà-oòrùn.
Láti Janoa ó yípo lọ sí gúúsù sí Atarotu àti Naara, ó sì dé Jeriko, ó sì pín sí odò Jordani.
Láti Tapua ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Rafini, ó sì parí ní Òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.
Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Efraimu tí ó wà ní àárín ìní àwọn ọmọ Manase.