Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Treason: Jesus falsely accused of

10 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Jesus falsely accused of

  1. Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”

  2. wọ́n sì hun adé ẹ̀gún. Wọ́n sì fi dé e lórí. Wọ́n sì fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ọba. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe ẹlẹ́yà pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!”

  3. Wọ́n sì tu itọ́ sí i lójú àti ara, wọ́n gba ọ̀pá wọ́n sì nà án lórí.

  4. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.”

  5. Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?” Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.”

  6. Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe: Èyí ni Ọba àwọn Júù.

  7. Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.”

  8. Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà: Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”

  9. Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kesari.”

  10. Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, Jesu ti Nasareti Ọba àwọn Júù.