Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tradition

52 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.

  2. Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”

  3. Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

  4. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan.

  5. Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi.

  6. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín.

  7. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi.

  8. Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”

  9. wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

  10. Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín?

  11. Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’

  12. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi,’

  13. tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín.

  14. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

  15. “ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.

  16. Lásán ni ìsìn wọn; nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

  17. Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, ó wí pé, “Ẹ tẹ́tí, ẹ sì jẹ́ kí nǹkan tí mo sọ yé yín.

  18. Ènìyàn kò di aláìmọ́ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ní di aláìmọ́.”

  19. Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisi lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí?”

  20. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò,

  21. ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.”

  22. Peteru wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”

  23. Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”?

  24. “Ẹyin kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde?

  25. Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.