Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Vine: Frequently made unfruitful as a punishment

5 ẹsẹ · 42 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Frequently made unfruitful as a punishment

  1. “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni Olúwa wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”

  2. Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.

  3. Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.

  4. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

  5. Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”