Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribe Of Gad: Land of, seized by the Moabites and Ammonites
Àwọn ẹsẹ nípa Land of, seized by the Moabites and Ammonites
“Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni, nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran, ìwọ tí ń gbé ní Aroeri. Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’
Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀. Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe! Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé, a pa Moabu run.
Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ, sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati,
sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu,
sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni,
sórí Kerioti àti Bosra, sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn.