Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Levites

255 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.

  3. Kékeré àti àgbà bákan náà, olùkọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ti akẹ́kọ̀ọ́, ṣẹ́ kèké fún iṣẹ́ wọn.

  4. Kèké èkínní èyí tí ó jẹ́ ti Asafu, jáde sí Josẹfu, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá èkejì sì ni Gedaliah, òun àti àwọn ìdílé rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, méjìlá

  5. ẹlẹ́ẹ̀kẹta sí Sakkuri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé, méjìlá

  6. ẹlẹ́ẹ̀kẹrin sí Isiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  7. ẹlẹ́ẹ̀karùnún sí Netaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  8. ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sí Bukkiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  9. ẹlẹ́ẹ̀keje sí Jasarela, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  10. ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí Jeṣaiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  11. ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án sí Mattaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  12. ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá sí Ṣimei, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá

  13. ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá sí Asareeli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  14. ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sí Haṣabiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  15. ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá sí Ṣubaeli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  16. ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sí Mattitiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  17. ẹlẹ́ẹ̀kẹẹ̀dógún sí Jerimoti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  18. ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlógún sí Hananiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  19. ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlógún sí Joṣbekaṣa, àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  20. ẹlẹ́ẹ̀kejìdínlógún sí Hanani, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  21. ẹlẹ́ẹ̀kọkàndínlógún sí Malloti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  22. ogún sí Eliata, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  23. ẹlẹ́ẹ̀kọkànlélógún sí Hotiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  24. ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógún sí Giddalti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá

  25. ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlélógún sí Mahasiotu, àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá