Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Levites

255 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún Olúwa láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ Olúwa fún Aaroni àlùfáà.

  2. Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín Olúwa èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’

  3. “Sọ fún àwọn ọmọ pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín.

  4. Ìwọ àti àwọn ìdílé rẹ̀ le jẹ èyí tí ó kù ní ibikíbi gbogbo. Nítorí pé ó jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ rẹ níbi àgọ́ ìpàdé.

  5. Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú.’ ”

  6. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti fún àwọn Lefi ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Israẹli yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú.

  7. Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.

  8. “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ (1,500 ẹsẹ̀ bàtà) láti ògiri ìlú náà.

  9. Lẹ́yìn ìlú náà, wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà àríwá, kí ìlú náà sì wà ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.

  10. “Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ààbò, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì ìlú sí i.

  11. Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjìdínláàádọ́ta ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

  12. Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”

  13. Ní ti Lefi ó wí pé, “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní Massa, ìwọ bá jà ní omi Meriba.

  14. Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, ‘Èmi kò buyì fún wọn.’ Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.

  15. Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀ àti Israẹli ní òfin rẹ̀. Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.

  16. Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa, kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i; àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

  17. Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún ṣíṣọ́ ààfin ọba.

  18. Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn huri, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní ṣíṣọ́ ilé tí a kọ́,

  19. àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yòókù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba.

  20. Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbọdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”

  21. Olórí àwọn ọ̀rọ̀ọ̀rún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti pa á láṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jehoiada àlùfáà.

  22. Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

  23. Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.

  24. Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

  25. Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn.