Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Happiness of the Wicked

24 ẹsẹ · 25 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Hamani jáde lọ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí Mordekai ní ẹnu-ọ̀nà ọba, ó wòye pé kò dìde tàbí kí ó bẹ̀rù ní iwájú òun, inú bí i gidigidi sí Mordekai.

  2. Ṣùgbọ́n, Hamani kó ara rẹ̀ ní ìjánu, ó lọ sí ilé. Ó pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jọ àti Sereṣi ìyàwó rẹ̀

  3. Hamani gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọlá fún un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tókù lọ.

  4. títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

  5. Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

  6. Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!

  7. Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

  8. Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.

  9. Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.

  10. Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso.

  11. Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’

  12. “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí.

  13. Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’

  14. “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’

  15. “Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́.

  16. Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju,

  17. Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun, àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá.

  18. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;

  19. Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.

  20. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

  21. “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

  22. Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba.

  23. Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!”

  24. Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.