Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Atonement: Foretold

12 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Foretold

  1. Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

  2. Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

  3. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.

  4. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

  5. A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

  6. Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

  7. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.

  8. Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

  9. “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan Ibi Mímọ́ Jùlọ.

  10. “Nítorí náà, mọ èyí pé, láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé, ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.

  11. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi, ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.

  12. Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”