Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Snow

8 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.

  2. Tí ó dúdú nítorí omi dídì, àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.

  3. Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,

  4. Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’ àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’

  5. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.

  6. “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,” ni Olúwa wí. “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  7. Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta? Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù, tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?

  8. Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí safire.