Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sieges

134 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọn yóò wa dojúkọ ọ pẹ̀lú ohun ìjà, kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹrù àti pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ ènìyàn; wọn yóò mú ìdúró wọn lòdì sí ọ ní gbogbo ọ̀nà pẹ̀lú asà ńlá àti kékeré pẹ̀lú àṣíborí. Èmi yóò yí ọ padà sí wọn fun ìjìyà, wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ gẹ́gẹ́ bí wọn tí tó.

  2. Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ.

  3. Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.

  4. “Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn.

  5. Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.

  6. Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ, ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun, nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.

  7. Pọn omi nítorí ìhámọ́, mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.

  8. Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo.

  9. “Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀.