Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sieges: Often suffered from famine

6 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Often suffered from famine

  1. Gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli ti ń kọjá lọ lórí odi, obìnrin kan sọkún sí i pé, “Ràn mí lọ́wọ́, olúwa ọba mi!”

  2. Ọba sì dá a lóhùn pé, “Bí Olúwa kò bá gbà ọ́, níbo ni èmi yóò gbé ti gbà ọ́? Láti inú ilẹ̀ ìpakà, tàbí láti inú ibi ìfúntí?”

  3. Nígbà náà ọba béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” Obìnrin náà dáhùn pé, “Obìnrin yìí wí fún mi pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ ẹ́ lónìí, ní ọ̀la àwa yóò jẹ ọmọkùnrin tèmi.’

  4. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ọmọkùnrin mi a sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ kejì mo wí fún un pé, ‘Mú ọmọkùnrin rẹ wá kí àwa kí ó lè jẹ,’ ṣùgbọ́n ó ti gbé e pamọ́.”

  5. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.

  6. Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni èmi yóò ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.