Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Probation: Solomon

11 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Solomon

  1. Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”

  2. “Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́,

  3. Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

  4. “Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,

  5. nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè.

  6. Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’

  7. Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”

  8. Olúwa bínú sí Solomoni nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì.

  9. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Solomoni kí ó má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Solomoni kò pa àṣẹ Olúwa mọ́.

  10. Nítorí náà Olúwa wí fún Solomoni pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pàṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmíràn.

  11. Ṣùgbọ́n, nítorí Dafidi baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ. Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ.