Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Polytheism

13 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Nígbà tí Labani sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rakeli sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.

  2. Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.

  3. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu.

  4. Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí, ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.

  5. Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”

  6. nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti.

  7. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah.

  8. Nígbà náà ni wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí ó wà láàrín wọn kúrò wọ́n sì sin Olúwa nìkan, ọkàn rẹ̀ kò sì le gbàgbé ìrora Israẹli mọ́.

  9. Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀.

  10. Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà? Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.

  11. Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’

  12. Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún. (Ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.)

  13. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa).