Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Phylactery

10 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ṣíṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí àmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.

  2. Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.”

  3. Gbọ́ ìwọ Israẹli, Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ni.

  4. Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ.

  5. Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín.

  6. Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.

  7. Ẹ so wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín.

  8. Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.

  9. Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín.

  10. “Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni. Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i.