Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Othniel

13 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.”

  2. Otnieli ọmọ Kenasi, arákùnrin Kalebu, sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

  3. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

  4. Ó sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.

  5. Èyí ni ilẹ̀ ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bi ìdílé wọn.

  6. Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.”

  7. Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

  8. Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu-Naharaimu bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Israẹli sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

  9. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

  10. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu.

  11. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.

  12. Àwọn ọmọ Kenasi: Otnieli àti Seraiah. Àwọn ọmọ Otnieli: Hatati àti Meonotai.

  13. Meonotai sì ni baba Ofira. Seraiah sì jẹ́ baba Joabu, baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.