Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Oil: Sacred

11 ẹsẹ · 49 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Sacred

  1. “Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kilogiramu mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì,

  2. kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lita mẹ́rin).

  3. Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe. Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.

  4. òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́. “Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”

  5. òróró olifi fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

  6. Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà.

  7. Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.

  8. Ó sì túnṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí—iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

  9. pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

  10. “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí. Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”

  11. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀.