Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Oil

97 ẹsẹ · 49 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òróró olifi fún iná títàn; òróró olóòórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóòórùn dídùn;

  2. “Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀.

  3. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí.

  4. “Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kilogiramu mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì,

  5. kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lita mẹ́rin).

  6. Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe. Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.

  7. Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀.

  8. Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

  9. Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

  10. òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́. “Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”

  11. òróró olifi fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

  12. Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà.

  13. Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.

  14. Ó sì túnṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí—iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

  15. pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

  16. “ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára, àkàrà tí a ṣe láìní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láìní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò.

  17. Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti ṣe ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà.

  18. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹbọ ohun jíjẹ yálà a fi òróró pò ó tàbí èyí tó jẹ́ gbígbẹ, wọ́n jẹ́ ti gbogbo ọmọ Aaroni.

  19. “Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àgbò aláìlábùkù méjì àti abo ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pòpọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n lógù òróró kan.

  20. “Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹ̀bi, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òsùwọ̀n lógù òróró

  21. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara olifi wá láti fi tan iná, kí fìtílà lè máa jò láì kú.

  22. Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

  23. Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́.

  24. “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí. Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”

  25. nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná pẹ̀lú ìdámẹ́rin òsùwọ̀n òróró wá síwájú Olúwa.