Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Net: Figurative

21 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Figurative

  1. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n, ó sì rìn lórí okùn dídẹ.

  2. kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

  3. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́; ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.

  4. Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.

  5. Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

  6. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi.

  7. Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi, ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.

  8. Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì. Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀; kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.

  9. Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi: a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú, wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi: ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.

  10. Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa.

  11. Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.

  12. Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.

  13. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.

  14. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.

  15. Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì, tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n, ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

  16. Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé, gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

  17. Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn.

  18. Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

  19. Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.

  20. Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá.

  21. Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.