Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mordecai: Promoted in Haman's place

6 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Promoted in Haman's place

  1. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ahaswerusi fún Esteri ayaba ní ilé e Hamani, ọ̀tá àwọn Júù. Mordekai sì wá síwájú ọba, nítorí Esteri ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba.

  2. Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani.

  3. Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.

  4. Ọba Ahaswerusi sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù òkun.

  5. Gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Mordekai ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Media àti ti Persia?

  6. Mordekai ará Júù ni ó jẹ́ igbákejì ọba Ahaswerusi, ó tóbi láàrín àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìre àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.