Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Love to Christ

15 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ, ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?

  2. Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.

  3. Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò.

  4. Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń sàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.

  5. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí tí ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.

  6. Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká. Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

  7. Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mabu tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára. Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.

  8. Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátápátá. Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu. Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.

  9. Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu,

  10. lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un.

  11. Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í.

  12. Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnra rẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ.

  13. Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

  14. Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?” Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

  15. Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.