Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Leah: Children of

15 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Children of

  1. Nígbà tí Olúwa sì ri pé, Jakọbu kò fẹ́ràn Lea, ó ṣí i ni inú ṣùgbọ́n Rakeli yàgàn.

  2. Lea sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Reubeni, nítorí ó wí pé, “Nítorí Olúwa ti mọ ìpọ́njú mi, dájúdájú, ọkọ mi yóò fẹ́ràn mi báyìí.”

  3. Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Simeoni, wí pé, “Nítorí tí Olúwa ti gbọ́ pé a kò fẹ́ràn mi, ó sì fi èyí fún mi pẹ̀lú.”

  4. Ó sì tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni ọkọ mi yóò fi ara mọ́ mi, nítorí tí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un,” nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Lefi.

  5. Ó sì tún lóyún, ó sì tún jẹ́ pé ọmọkùnrin ni ó bí, ó sì wí pé, “Nígbà yìí ni èmi yóò yin Olúwa.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Juda. Ó sì dáwọ́ ọmọ bíbí dúró.

  6. Nígbà tí Lea sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Silipa fún Jakọbu bí aya.

  7. Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu.

  8. Nígbà náà ni Lea wí pé, “Orí rere ni èyí!” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Gadi.

  9. Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì tún bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu.

  10. Nígbà náà ni Lea wí pé, “Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Aṣeri.

  11. Ọlọ́run sì gbọ́ ti Lea, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jakọbu.

  12. Nígbà náà ni Lea wí pé, “Ọlọ́run ti sẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isakari.

  13. Lea sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jakọbu.

  14. Nígbà náà ni Lea tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Sebuluni.

  15. Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dina.