Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Law

175 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.

  2. Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn,

  3. fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

  4. Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀.

  5. Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́, nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.”

  6. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  7. Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì.

  8. Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé, “Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.

  9. Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí.

  10. Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.

  11. Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Olúwa,’ nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékeré dé àgbà.

  12. Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”

  13. Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.

  14. Ẹ̀mí Mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà Ibi Mímọ́ Jùlọ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkínní bá sì dúró,

  15. èyí tí i ṣe àpẹẹrẹ fún ìgbà ìsinsin yìí. Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé.

  16. Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí í ṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe.

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí.

  18. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa.

  19. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:

  20. mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?

  21. Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ìlérí ogún àìnípẹ̀kun gbà.

  22. Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú;

  23. nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ́yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú, nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láààyè.

  24. Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú pàápàá sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀.

  25. Nítorí nígbà tí Mose ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísópù ó sì fi wọ́n àti ìwé pàápàá àti gbogbo ènìyàn.