Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Lamentations

25 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀. Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká, ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.

  2. Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ; mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.

  3. Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ; ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.

  4. “Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli

  5. wí pé: “ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù? Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.

  6. Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.

  7. Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn. Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.

  8. “ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.

  9. Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.

  10. Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro. Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.

  11. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i, àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá. Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.

  12. Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.

  13. “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀; tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

  14. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.

  15. Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú, á sì wọ́ ọ lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀, ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ iná sì jó wọn run.

  16. Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.

  17. Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”

  18. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà, o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà.

  19. Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ; sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì, àti jasperi, safire, emeradi, turikuose, àti karbunkili, àti wúrà, ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà, láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.

  20. A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, torí èyí ni mo fi yàn ọ́. Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run; ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná.

  21. Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ, láti ọjọ́ tí a ti dá ọ, títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.

  22. Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ, ìwọ kún fún ìwà ipá; ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù, bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run. Èmi sì pa ọ run, ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.

  23. Ọkàn rẹ gbéraga, nítorí ẹwà rẹ. Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́, nítorí dídára rẹ. Nítorí náà mo le ọ sórí ayé; mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.

  24. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ, ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́. Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá, láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run, èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀, lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

  25. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n, ní ẹnu ń yà sí ọ; ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”