Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Industry

46 ẹsẹ · 23 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!

  2. Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba,

  3. síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.

  4. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.

  5. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

  6. Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;

  7. nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.

  8. Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé

  9. àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.

  10. Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

  11. Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá, síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.

  12. Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá; síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;

  13. àwọn eṣú kò ní ọba, síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

  14. Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú, síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

  15. Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.

  16. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.

  17. Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.

  18. Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.

  19. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.

  20. Ó rí i pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.

  21. Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.

  22. O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.

  23. Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.

  24. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.

  25. A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.