Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Horn

43 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá.

  2. “Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  3. “Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.

  4. Odò iná ń sàn, ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá. Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un; ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀. Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀.

  5. “Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.

  6. A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yòókù, ṣùgbọ́n a fún wọn láààyè láti wà fún ìgbà díẹ̀.

  7. “Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.

  8. A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.

  9. “Ọkàn èmi Daniẹli, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.

  10. Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí. “Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi:

  11. ‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé.

  12. Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’

  13. “Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtumọ̀ òtítọ́ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yòókù, èyí tí ó dẹ́rùba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀ àti nípa ìwo yòókù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  15. Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn,

  16. títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba.

  17. “Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé, ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé. Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yòókù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́.

  18. Ìwo mẹ́wàá ni ọba mẹ́wàá tí yóò wá láti inú ìjọba yìí. Lẹ́yìn tí wọn ní ọba mìíràn yóò dìde, ti yóò yàtọ̀ sí tí àwọn ti ìṣáájú, yóò sì borí ọba mẹ́ta.

  19. Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, àwọn ìwo náà sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.

  20. Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, sí àríwá, àti sí gúúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó le è dojúkọ ọ́, kò sí ẹnìkan tí ó le è yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.

  21. Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrín ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láìfi ara kan ilẹ̀.

  22. Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, ó sì dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára.

  23. Mo rí i tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojúkọ ọ́, Òbúkọ náà kàn án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì ṣí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.

  24. Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.

  25. Lára ọ̀kan nínú wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúúsù, àti sí ìhà ìlà-oòrùn àti sí ilẹ̀ dídára.