Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Form: Irregularity in

10 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Irregularity in

  1. Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì.

  2. Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu.

  3. Ọ̀rọ̀ náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

  5. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa.

  6. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù,

  7. tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́

  8. Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.

  9. Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

  10. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan.