Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ephesus: Apollos visits and preaches in
Àwọn ẹsẹ nípa Apollos visits and preaches in
Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea, nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.
Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Efesu, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀.
Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀.
Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì lọ kúrò láti Efesu.
Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Kesarea, ó gòkè lọ si Jerusalẹmu láti kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Antioku.
Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀, ó n lọ, láti káàkiri ni agbègbè Galatia àti Frigia, o ń mu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le.
Júù kan sì wà tí a ń pè ni Apollo, tí a bí ni Alekisandiria, ó wá sí Efesu. Ó ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀.
Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu dáradára; kìkì bamitiisi tí Johanu ní ó mọ̀.
Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sinagọgu. Nígbà tí Akuila àti Priskilla gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀, wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.
Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Akaia, àwọn arákùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kí wọ́n gbà á, nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ púpọ̀.
Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé mímọ́ pé, Jesu ni Kristi.