Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Claudius Lysias: A Roman military officer

18 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa A Roman military officer

  1. Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú.

  2. Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu.

  3. Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe.

  4. Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun.

  5. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn.

  6. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”

  7. Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Paulu wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Giriki bí?

  8. Ìwọ ha kọ ní ara Ejibiti náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ sí ijù?”

  9. Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”

  10. Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé,

  11. Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run,

  12. olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Paulu wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun ba à lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.

  13. Bí wọ́n sí tí fi ọṣán dè é, Paulu bí balógun ọ̀rún tí ó dúró tì í pé, “Ó ha tọ́ fún yín láti na ẹni tí i ṣe ará Romu ni àìdálẹ́bi bí?”

  14. Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Romu ní i ṣe?”

  15. Alábojútó-ogun sì dé, ó sì bí Paulu pé, “Sọ fún mi, ará Romu ni ìwọ jẹ́ bí?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

  16. Alábojútó-ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.” Paulu wí pé, “Ṣùgbọ́n a bí mi sínú rẹ̀ ni.”

  17. Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fàsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Olórí ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Romu ní Paulu i ṣe, àti nítorí ó tí dè é.

  18. Ní ọjọ́ kejì, nítorí tí olórí ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Paulu sùn sí, ó tú u sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Paulu sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró níwájú wọn.