Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Captivity

14 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. títí tí Olúwa fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni a kó gbogbo ènìyàn Israẹli kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí ìgbèkùn ni Asiria, títí di òní yìí.

  2. Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.

  3. Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í.

  4. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Asiria gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Samaria ní ọdún kẹfà Hesekiah tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsànán Hosea ọba Israẹli.

  5. Ọba Asiria lé Israẹli kúrò ní Asiria, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hala, ní Gosani létí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

  6. Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.

  7. bẹ́ẹ̀ ni, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín wọn; Èmi yóò ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ.

  8. Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí.

  9. Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí.

  10. Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Juda lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi. Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́ ibi tí kò ti le sá àsálà.

  11. Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn, àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú, òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.

  12. Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀, nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú, ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

  13. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Israẹli lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì ṣubú nípasẹ̀ idà.

  14. Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ́ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.