Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Altars: Of Ahaz
Àwọn ẹsẹ nípa Of Ahaz
Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.
Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku.
Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀.