Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Adaiah
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Josiah jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jedida ọmọbìnrin Adaiah; ó wá láti Boskati.
ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,
Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.
Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah; àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri.
Ní ọdún keje, Jehoiada fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún kan, Asariah ọmọ Jerohamu, Iṣmaeli ọmọ Jehohanani Asariah ọmọ Obedi, Maaseiah ọmọ Adaiah àti Elisafati ọmọ Sikri.
Nínú àwọn ìran Bani: Meṣullamu, Malluki, Adaiah, Jaṣubu, Ṣeali àti Jerimoti.
Ṣelemiah, Natani, Adaiah,
àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo.
àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹmpili jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnlélógún (822) ọkùnrin: Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaiah, ọmọ Amisi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah,