- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Deuteronomi 29:26nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn.
- Deuteronomi 29:27nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ìbínú Olúwa ru sí ilẹ̀ wọn, dé bi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀.
- Deuteronomi 29:28nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ní ìbínú àti ní ìkáàánú, àti ní ìrunú ńlá, Olúwa sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí.”
- Deuteronomi 29:29nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fihàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
- Deuteronomi 30:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
- Deuteronomi 30:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí.
- Deuteronomi 30:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí.
- Deuteronomi 30:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà.
- Deuteronomi 30:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. Olúwa yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ.
- Deuteronomi 30:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ.
- Deuteronomi 30:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú gbogbo ègún yín wá sórí àwọn ọ̀tá à rẹ tí wọ́n kórìíra àti tí wọ́n ṣe inúnibíni rẹ.
- Deuteronomi 30:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò tún gbọ́rọ̀ sí Olúwa àti tẹ̀lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí.
- Deuteronomi 30:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.
- Deuteronomi 30:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.
- Deuteronomi 30:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nítorí àṣẹ yìí tí mo pa fún ọ lónìí, kò ṣòro jù fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò kọjá agbára rẹ.
- Deuteronomi 30:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?”
- Deuteronomi 30:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì Òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?”
- Deuteronomi 30:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí rẹ, ó wà ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é.
- Deuteronomi 30:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Wò ó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun.
- Deuteronomi 30:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ní èyí tí mo pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa pa àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè yè, kí ó sì máa bí sí i, kí Olúwa Ọlọ́run lè bù si fún ọ ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ìwọ ń lọ láti gbà á.
- Deuteronomi 30:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n,
- Deuteronomi 30:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní.
- Deuteronomi 30:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ,
- Deuteronomi 30:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.
- Deuteronomi 31:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Mose jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Israẹli pé,