- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 930–586 BC
The Divided Kingdom
The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Ọba 20:4nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé:
- 2 Ọba 20:5nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
“Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
- 2 Ọba 20:6nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi.’ ”
- 2 Ọba 20:7nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Isaiah wí pé, “Mú odidi ọ̀pọ̀tọ́.” Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fi lé oówo náà, ara rẹ̀ sì yá.
- 2 Ọba 20:8nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Hesekiah sì béèrè lọ́wọ́ Isaiah pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”
- 2 Ọba 20:9nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Isaiah dáhùn pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”
- 2 Ọba 20:10nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
“Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá,” Hesekiah wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”
- 2 Ọba 20:11nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nígbà náà wòlíì Isaiah ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Ahasi.
- 2 Ọba 20:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli ránṣẹ́ ìwé àti ẹ̀bùn sí Hesekiah nítorí tí ó ti gbọ́ nípa àìsàn Hesekiah.
- 2 Ọba 20:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Hesekiah gba ìránṣẹ́ náà ó sì fihàn wọ́n, gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé ìṣúra—sílífà, àti wúrà, àti tùràrí, àti òróró dáradára àti ìhámọ́ra àti gbogbo èyí tí a rí lára ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan nínú ààfin rẹ̀ tàbí nínú gbogbo ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò sì fihàn wọ́n.
- 2 Ọba 20:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Isaiah wòlíì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ọkùnrin náà sọ, àti níbo ni wọ́n ti ń bọ̀ wá?” “Láti ìlú jíjìn réré,” Hesekiah dáhùn. “Wọ́n wá láti Babeli.”
- 2 Ọba 20:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wòlíì náà béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ní ààfin rẹ?” “Wọ́n rí gbogbo nǹkan ní ààfin mi,” Hesekiah wí pé. “Kò sí nǹkan kan lára àwọn ìṣúra tí èmi kò fihàn wọ́n.”
- 2 Ọba 20:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Isaiah wí fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
- 2 Ọba 20:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ òní, wọn yí ó gbe lọ sí Babeli, kò sí ohun tí yóò kù, ni Olúwa wí.
- 2 Ọba 20:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àti díẹ̀ nínú àwọn ìran rẹ, ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀, tí wọn yóò bí fún ọ, ni wọn yóò kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babeli.”
- 2 Ọba 20:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Hesekiah wí fún Isaiah pé. “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò wí pé, “Kò ha dára àlàáfíà àti òtítọ́ ní ọjọ́ ayé mi?”
- 2 Ọba 20:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ní ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tókù nípa ìjọba Hesekiah, gbogbo ohun tí ó ṣe tan àti bí ó ti ṣe adágún omi àti ọ̀nà omi náà nípa èyí tí ó gbé wá omi sínú ìlú ńlá, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìgbésẹ̀ ayé àwọn ọba àwọn Juda?
- 2 Ọba 20:21nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Hesekiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀: Manase ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
- 2 Ọba 21:1nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba.
- 2 Ọba 21:2nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
- 2 Ọba 21:3nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.
- 2 Ọba 21:4nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.”
- 2 Ọba 21:5nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú.
- 2 Ọba 21:6nǹkan bí 683 ṣáájú Kristi
Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.
- 2 Ọba 21:7nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi
Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé.