Fò sí àkóónú

Bethel

62 verses · 3 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Beth-el, house

31.9300, 35.2200 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Bethel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Beteli àti Ai jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123)

  2. Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀.

  3. Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi, bí ojú ti í ti ilé Israẹli nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.

  4. Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli, nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà, a o pa ọba Israẹli run pátápátá.

  5. Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀, o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀. Ó bá Olúwa ní Beteli, Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,

  6. “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.

  7. “Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀; ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta.

  8. ẹ má ṣe wá Beteli, ẹ má ṣe lọ sí Gilgali, ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba. Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn, A ó sì sọ Beteli di asán.”

  9. Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè, kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu a sì jó o run Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.

  10. Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  11. Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.”

  12. Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa.