Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni, a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ, tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ.

  2. Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ, èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ, ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ, pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

  3. “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.

  4. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu.

  5. Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”

  6. Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  7. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ. Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”

  8. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ, àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.

  9. Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ: ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè. Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

  10. Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni Olúwa. “ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli.

  11. “ ‘Nítorí náà, èyí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ.

  12. Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa. “ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,”

  13. nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi.

  14. Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

  15. “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí.

  16. Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.

  17. Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

  18. Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

  19. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  20. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.

  21. Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

  22. “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

  23. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé:

  24. “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Hu, kí o sì wí pé, “Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”

  25. Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú, àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí.