Fò sí àkóónú

Elijah

92 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Elias

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Elijah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Elijah sì wí fún Ahabu pé, “Lọ, jẹ, kí o sì mu, nítorí ìró ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò ń bọ̀.”

  2. Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu gòkè lọ láti jẹ àti láti mu. Ṣùgbọ́n Elijah gun orí òkè Karmeli lọ ó sì tẹríba, ó sì fi ojú rẹ̀ sí agbede-méjì eékún rẹ̀.

  3. Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Elijah; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì sáré níwájú Ahabu títí dé Jesreeli.

  4. Ahabu sì sọ gbogbo ohun tí Elijah ti ṣe fún Jesebeli àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì.

  5. Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.”

  6. Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?”

  7. Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà. Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?”

  8. Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó.

  9. Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Elijah sì dáhùn wí pé, “Padà sẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?”

  10. Eliṣa sì fi í sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Elijah lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

  11. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé,

  12. Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.

  13. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé,

  14. Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa wí fún Elijah ará Tiṣibi pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Samaria kí o sì béèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu òrìṣà Ekroni?’

  15. Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ní èyí, ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ.

  16. Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.” Ọba sì wí pé, “Elijah ará Tiṣibi ni.”

  17. Elijah sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

  18. “Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀.

  19. Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ!

  20. Angẹli Olúwa sọ fún Elijah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba.

  21. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Elijah ti sọ. Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda.

  22. Nígbà tí Olúwa ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali.

  23. Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Beteli.” Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli.

  24. Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: Olúwa ti rán mi lọ sí Jeriko.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko.

  25. Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jordani.” Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.