Fò sí àkóónú

Benjamin

157 ẹsẹ · 26 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Benjamin

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Fọn fèrè ní Gibeah, kí ẹ sì fun ìpè ní Rama. Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni; máa wárìrì, ìwọ Benjamini.

  2. Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria; Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.

  3. A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba.

  4. Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún.

  5. Ǹjẹ́ mo ní, Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini.

  6. ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi;

  7. Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000). Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà (12,000).