Skip to content
Onidajọ 20:18-48

Onidajọ 20:18-48

18
Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.”
19
Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah).
20
Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah.
21
Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà.
22
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.
23
Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”
24
Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì.
25
Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.
26
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa.
27
Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀,
28
Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”
29
Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sá pamọ́ yí Gibeah ká.
30
Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí.
31
Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah.
32
Nígbà tí àwọn Benjamini ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”
33
Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Baali-Tamari, àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí wọ́n sá pamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn Gibeah.
34
Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Israẹli gbógun ti Gibeah láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Benjamini kò funra pé ìparun wà nítòsí.
35
Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá méjìlá ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,100) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun.
36
Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn. Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah.
37
Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà.
38
Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà,
39
nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun. Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.”
40
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.
41
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Benjamini nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu.
42
Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ Israẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀.
43
Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Benjamini ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn Gibeah.
44
Ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun.
45
Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọkùnrin ṣubú.
46
Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun.
47
Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin.
48
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options