Gẹnẹsisi 31:22-29
22
Ní ọjọ́ kẹta ni Labani gbọ́ pé Jakọbu ti sálọ.
23
Ó sì mú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì lépa Jakọbu, ó sì lépa wọn fún ọjọ́ méje, ó sì bá wọn ní òkè Gileadi.
24
Ọlọ́run sì yọ sí Labani ará Aramu lójú àlá ní òru, ó sì wí fun un pé, “Ṣọ́ra, má ṣe sọ ohunkóhun fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.”
25
Jakọbu ti pa àgọ́ rẹ̀ si orí òkè kan, nígbà tí Labani bá a. Labani àti àwọn tí ó wá pẹ̀lú rẹ̀ sì pàgọ́ tì wọ́n sí ilẹ̀ òkè Gileadi.
26
Nígbà náà ni Labani wí fún Jakọbu pé, “Èwo ni ìwọ ṣe yìí? Tí ìwọ sì tàn mi, ó sì kó àwọn ọmọbìnrin mi bi ìgbèkùn tí a fi idà mú.
27
Èéṣe tí ìwọ yọ́ lọ tí ìwọ sì tàn mi? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé ìwọ ń lọ, kí èmi fi ayọ̀ àti orin, pẹ̀lú ìlù àti ohun èlò orin sìn ọ́.
28
Ìwọ kò tilẹ̀ jẹ́ kí èmi fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ mi lẹ́nu, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi pé ó dìgbà? Ìwọ ṣiwèrè ní ohun tí ìwọ ṣe yìí.
29
Mo ní agbára láti ṣe ọ ni ibi, ṣùgbọ́n ní òru àná, Ọlọ́run baba rẹ sọ fún mi pé, kí èmi ṣọ́ra, kí èmi má ṣe sọ ohun kan fún Jakọbu, ìbá à ṣe rere tàbí búburú.
Settings