Eksodu 10:1-11
1
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, mo ti ṣé àyà Farao le àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí èmi kí o ba le ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrín wọn.
2
Kí ẹ̀yin ki ó le sọ fún àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ ọmọ yín; bí mo ti jẹ àwọn ará Ejibiti ní yà àti bí mo ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn. Kí ìwọ ba á le mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.”
3
Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, tiwọn sí wí fún un pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn Heberu sọ, ‘Yóò ti pẹ́ to ti ìwọ yóò kọ̀ láti tẹrí ara rẹ ba ní iwájú mi? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó sìn mi.
4
Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn lọ, èmi yóò mú eṣú wa sí orílẹ̀-èdè rẹ ní ọ̀la.
5
Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ.
6
Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Ejibiti. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mose pẹ̀yìndà kúrò níwájú Farao.
7
Àwọn ìjòyè Farao sọ fún un, “Yóò ti pẹ́ to tí ọkùnrin yìí yóò máa jẹ́ ìkẹ́kùn fún wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí síbẹ̀ pé, ilẹ̀ Ejibiti ti parun tán?”
8
Nígbà náà ni a mú Aaroni àti Mose padà wá sí iwájú Farao ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”
9
Mose dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe àjọ fún Olúwa.”
10
Farao sì wí pé, “Mo fi Olúwa búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín.
11
Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yin ń béèrè fún.” Wọ́n sì lé Mose àti Aaroni kúrò ní iwájú Farao.
Settings