Eksodu 10:12-20
12
Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè lórí Ejibiti kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú bo gbogbo ilẹ̀, kí ó sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko wọn jẹ́, àní gbogbo ohun tí òjò yìnyín kò bàjẹ́ tan.”
13
Nígbà náà ni Mose na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Ejibiti, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú wá;
14
wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu eṣú bẹ́ẹ̀ rí, kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí.
15
Wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ tí ilẹ̀ fi di dúdú. Wọ́n ba gbogbo ohun tókù ní orí ilẹ̀ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́; gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ní inú oko àti gbogbo èso tí ó wà lórí igi. Kò sí ewé tí ó kù lórí igi tàbí lórí ohun ọ̀gbìn ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.
16
Farao yára ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín àti sí i yín pẹ̀lú.
17
Nísinsin yìí ẹ dáríjì mi lẹ́ẹ̀kan sí i kí ẹ sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín kí ó lè mú ìpọ́njú yìí kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”
18
Nígbà náà ni Mose kúrò ní iwájú Farao ó sì gbàdúrà sí Olúwa.
19
Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
20
Síbẹ̀ Olúwa ṣe àyà Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.
Settings