Deuteronomi 2:1-9
1
Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí aginjù, a gba ọ̀nà Òkun Pupa, bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Seiri.
2
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé,
3
“Ẹ ti rìn yí agbègbè ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá.
4
Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Esau; àwọn ará Edomu tí ń gbé ní Seiri. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.
5
Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Seiri fún Esau gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.
6
Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”
7
Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ó ti mójútó ìrìnàjò yín nínú aginjù ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí, dé bi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.
8
Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Esau tí ń gbé ní Seiri. A yà kúrò ní ọ̀nà Arabah èyí tí ó wá láti Elati àti Esioni-Geberi, a sì rìn gba ọ̀nà aginjù Moabu.
9
Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Moabu bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi Ari fún àwọn ọmọ Lọti bí i ìní.”
Settings