Daniẹli 2:3-27
3
ọba sì wí fún wọn pé, “Mo ti lá àlá kan èyí tí ó mú kí ọkàn mi dàrú, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ àlá náà.”
4
Nígbà náà ni àwọn awòràwọ̀ dá ọba lóhùn ní èdè Aramaiki pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Sọ àlá yìí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àwa yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
5
Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, “Ohun náà ti kúrò lórí mi, tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn.
6
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀. Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”
7
Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀.”
8
Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi.
9
Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
10
Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀.
11
Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fihan ọba àfi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrín ènìyàn.”
12
Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Babeli run.
13
Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n.
14
Nígbà tí Arioku, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Babeli, Daniẹli sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye.
15
Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Arioku sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Daniẹli.
16
Nígbà náà ni Daniẹli wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba.
17
Nígbà náà ni Daniẹli padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananiah, Miṣaeli àti Asariah.
18
Ó sọ fún wọn pé kí wọn béèrè fún àánú Ọlọ́run, Olúwa ọ̀run, nítorí àṣírí yìí, kí Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má ba ṣègbé pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n Babeli yòókù, tí ó wà ní Babeli.
19
Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run
20
Daniẹli wí pé: “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé; tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára.
21
Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.
22
Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà.
23
Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”
24
Nígbà náà ni Daniẹli tọ́ Arioku lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Babeli run, Daniẹli wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Babeli run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sísọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”
25
Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”
26
Ọba béèrè lọ́wọ́ Daniẹli ẹni tí a tún ń pè ní Belṣassari pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”
27
Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings