Ìṣe àwọn Aposteli 9:1-30
1
Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí èémí ìhalẹ̀ mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ,
2
ó béèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí Sinagọgu tí ń bẹ ní ìlú Damasku pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni ọ̀nà yìí, ìbá à ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerusalẹmu.
3
Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súnmọ́ Damasku; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí i ká.
4
Ó sì ṣubú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Saulu, Saulu, èéṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”
5
Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?” Olúwa sì wí fún pé, “Èmi ni Jesu, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.
6
Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”
7
Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Saulu lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan.
8
Saulu sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Damasku.
9
Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.
10
Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!” Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”
11
Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà.
12
Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”
13
Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu.
14
Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”
15
Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli.
16
Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”
17
Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”
18
Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀.
19
Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun. Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀.
20
Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run.
21
Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”
22
Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.
23
Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á.
24
Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.
25
Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.
26
Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni.
27
Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu.
28
Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa.
29
Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.
30
Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu.
Settings