Skip to content
2 Timotiu 4:9-21

2 Timotiu 4:9-21

9
Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá.
10
Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia.
11
Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.
12
Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu.
13
Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.
14
Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
15
Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.
16
Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀, àdúrà mi ni kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn.
17
Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà.
18
Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
19
Kí Priska àti Akuila, àti ilé Onesiforu.
20
Erastu wà ní Kọrinti: ṣùgbọ́n mo fi Tirofimu sílẹ̀ ni Miletu nínú àìsàn.
21
Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù. Eubulu kí ọ, àti Pudeni, àti Linu, Klaudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options